Àṣìrò Náà

ebook Ìtọ́ni Ẹ̀mi Kan, Àjọ̀nnú Ẹkùn Kan, Pẹ̀lú Ìyá Kan Tí Ó Nkọni Lóminú

By Owen Jones

cover image of Àṣìrò Náà

Sign up to save your library

With an OverDrive account, you can save your favorite libraries for at-a-glance information about availability. Find out more about OverDrive accounts.

   Not today

Search for a digital library with this title

Title found at these libraries:

Loading...

Megan jẹ́ ọ̀dọ́mọdé alágbára, tí kò lè rí ẹnikẹ́ni láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti lóye àwọn agbára rẹ̀... kò sí alààyè kankan tí ó́́́́́́́́́́́́́́́́́́ yé.
'Àṣìrò Náà' jẹ́ ìtàn kúkúrú̀ kan nípa ọmọdébìnrin kan tí ó túbọ̀ ndá a mọ̀ pé òun lè ṣe àwọn nnkan tí ìkankan nínú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kò lè ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ilé-ìwé sọ pé wọ́n ní irú àwọn agbára àjèjì bẹ́ẹ̀. Orúkọ ọmọdébìnrin náà ni Megan, ó sì jẹ́ ọmọ ọdún méjìlà nínú èyí, tíí ṣe ìwé àkọ́kọ́. Megan ní àwọn ìṣòro méjì kan tí ó dàbí ẹni pé ọwọ́ ò ká. Àkọ́kọ́ ni pé àyà nfo ìyá rẹ̀ nípa áwọn agbara tí ó fi ara pamọ́ sínú ọmọbìnrin. Kìí ṣe pé òun kò níí ràn á lọ́wọ́ nìkan, ṣùgbọ́n yóò dìídì da omi tútù síi lọ́kàn. Ìṣòro kejì ni pé òun kò lè rí olùkọ́ kan tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún u láti mú kí àwọn agbára rẹ̀ tí ó rékọjá ti ìṣẹ̀dá, tí ó ṣàjèjì dàgbà sókè. Ó gbìyànjú láti bá ìyá rẹ̀ sọ ọ́, ṣùgbọ́n ìjẹ́wọ́ tí ó kúrú jọjọ ni ó nṣe; kò sì tilẹ̀ kà á sí láti sọ fún baba rẹ̀, nítorí pé ó mọ̀ pé ìyá òun ò níí fi ọwọ́ síi àti pé lẹ́yìn-ò-rẹyìn, Megan kò fẹ́ ṣẹ ìyá rẹ̀. Megan nní ìmọ̀lára pé ìdìpọ̀ kan tí wọ́n jọ mọ̀ sínú wà láárín òun àti ìyá òun. Kí a kúkú sọ pé ìdìpọ̀ tí ó máa nwà láárín gbogbo ìyá àti ọmọ wọn obìnrin, ṣùgbọ́n bóyá ó tún jinlẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ bákan náà. Tani ó lè sọ, níwọ̀n ìgbà tí Megan fúnraarẹ̀ ò mọ̀? Kò mọ̀ ju pé ó dàbí ẹni pé ìyá òun ò máa kó ipa tí a nretí lọ́dọ̀ rẹ̀ láti kó gẹ́gẹ́ bí ìyá onífẹ̀ẹ́ fún ọmọbìnrin tí kò níí pẹ́ da ọ̀dọ́, tí ó ní àwọn àníyàn tí ó fẹ́, bẹ́ẹ̀kọ́, nílò láti bá ẹnìkan tí ó fi ọkàn tán sọ. Megan nfẹ́ láti fún ìyá rẹ̀ ní àkókò láti borí ìbẹ̀rù rẹ̀ nípa ohun tí ó jẹ́ kàyééfì náà. Ó lè dúró, ó tilẹ̀ lè fi ara da ìlòkúlò tí ó burú tí ojú rẹ̀ nrí ní ìkọ̀kọ̀ láì jẹ́ pé baba rẹ̀ mọ̀. Ó sá le ṣe ìyẹn fún sáà yìí. 'Àṣìrò Náà' ni àkọ́kọ́, níbi tí a dé yìí, nínú àwọn ìtàn kúkúrú mẹ́tàlélógún ní ọ̀wọ́ yìí nípa ìṣíníyè Megan síwájú síi bí ó ti nrí àwọn ènìyàn láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún u láti lóye ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti lóye tẹ̀ síwájú nípa ìdàgbàsókè rẹ̀ ní ti ìgbé aye tí ó taayọ ti ìṣẹ̀dá, ti ẹ̀mí àti èyí tí ó ṣàjèjì. Kìí ṣe pé wọ́n ní láti kọ́ ọ ní àwọn ohun tí ó ṣeéṣe nìkan àti bí yóò ti ṣe é, ṣùgbọ́n kínni ó yẹ kí ó fi àwọn àkànṣe agbára rẹ̀ ṣe. Ọmọ rere ni Megan, nítorí náà yóò dàbí ẹni pé yóò fẹ́ lo àwọn agbára rẹ̀ fún ire, ṣùgbọ́n kìí fi gbogbo ìgbà rọrùn láti ṣe ohun tí ó tọ́ bí o tilẹ̀ mọ ohun tí ìyẹn jẹ́. Àwọn ìtàn nípa Megan yìí yóò fa ẹnikẹ́ni mọ́ra tí ó ka àwọn agbára àjèjì, àwọn ohun tí ó taayọ ìṣẹ̀dá àti ohun kàyééfì sí tí ọjọ́ orí wọn sì wà láárín ọdún mẹ́wàá sí ọgọ́rún.

Àṣìrò Náà