Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan

ebook Atọ́nà Ẹ̀mí Kan, Ànjọ̀nnú Ẹkùn Kan Àti Ìyá Kan Tí Ó Kọni Lóminú!

By Owen Jones

cover image of Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan

Sign up to save your library

With an OverDrive account, you can save your favorite libraries for at-a-glance information about availability. Find out more about OverDrive accounts.

   Not today

Search for a digital library with this title

Title found at these libraries:

Loading...
Ìjádelọ ọlọ́dọọdún ilé-ìwé Megan mú òun àti àwọn ojúgbà rẹ̀ lọ sí àpapọ̀ sí àwọn àṣàpọ̀ ihò, tí àwọn ẹ̀yà tí ó wà ṣáájú ìtàn kíkọ fi nṣe ibùgbé. Ó dá Megan lójú pé òun nní ìmọ̀ síi nípa ohun tí ó dìídì ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí ó pẹ́ tó bẹ́yẹn nípa lílo àwọn agbára àìmọ̀ rẹ̀, ju ohun tí àwọn afinimọ̀nà tí wọ́n gbà fún wọn lè sọ fún wọn.
Megan jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàlá, tí ó ndá a mọ̀ pé òun ní àwọn agbára àìmọ̀ tí àwọn ẹlòmíràn ò ní. Ó kọ́kọ́ gbìyànjú láti bá ìyá rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn agbára náà, ṣùgbọ́n ó yọrí sì àwọn àbájáde tí ó burú. Nítorí náà, ó kọ́ bí a ti ndákẹ́ nípa wọn. Ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn kan fẹ́ ṣe ìrànlọ́wọ́ tí ẹranko kan sì fi ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pàtàkì hàn, ṣùgbọ́n wọn ò 'sí láàyè' tí a bá gbé e yẹ̀wò. Wọ́n ti kọ̀já lọ. Megan ní irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́yẹn: Wacinhinsha, tíí ṣe Atọ́nà Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ti jẹ́ ẹ̀yà Sioux nígbà tí ó wà láyé kẹ́yìn; baba ìyá rẹ̀, Gramps pẹ̀lú ẹkùn nlá ilẹ̀ Siberia kan tí wọ́n npè ní Grrr. Wacinhinsha ní ìmọ̀ tí ó taayọ nípa ohun gbogbo tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí, àìmọ̀ àti èyí tí ó kọjá òye ènìyàn. Baba ìyá rẹ̀ jẹ́ òpè 'olóògbé' tí Grrr sì lè sọ èdè Ẹkùn nìkan, bí ènìyàn ti lè fi ọgbọ́n gbé e. Nítòótọ́, èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú ìyẹn ni ò yé àwọn ènìyàn. Nínú ọ̀wọ́ yìí nínú ìgbé ayé Megan, wọ́n nkó òun pẹ̀lú ìyókù àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jọ nkẹ́kọ̀ọ́ papọ̀ ní ilé-ìwé jáde. Ó yẹ kí àwọn yìí jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ọlọ́dọọdún, ṣùgbọ́n kìí ṣe gbogbo ìgbà ni ilé-ìwé nní owó láti ná lé wọn lórí. Èyí jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún Megan bí ó ti nyọjú wo ìgbé ayé àwọn tí wọ́n ti wà láyé láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Ẹ fi ọkàn bá Megan lọ bí ó ti ngbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ síi láti ara ìjádelọ ilé-ìwé rẹ̀ nípa ìgbà àtijọ́ tí ó sì ngbọ́ ìmọ̀ràn tí Atọ́nà Ẹ̀mí rẹ̀ nfún u àti ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti ṣe ìyẹn.
PUBLISHER: TEKTIME
Ìrìnàjò Ilé-Ìwé Megan